E YO N’NU OLUWA, E YO
1. E yo n’nu Oluwa, e yo,
eyin t’okan re se dede
eyin t’o ti yan Oluwa,
le ‘banuje at’aro lo
Eyo! E yo!
E yo n’nu Oluwa, e yo!
E yo! E yo
E yo n’nu Oluwa, e yo!
2. E yo ‘tori On l’Oluwa
L’aye ati l’orun pelu
Oro Re bor’ohun gbogbo
O l’agbara lati gbala
3. ‘Gbat’ e ba nja ija rere,
Ti Ota f’ere bori yin
Ogun Olorun t’e ko ri
Po ju awon ota yin lo
4. B’okunkun tile yi o ka
Pelu isudede gbogbo
Mase je k’okan re damu
Sa gbeke l’Oluwa d’opin
5. E yo n’nu Oluwa, e yo
E korin iyin Re kikan
Fi duru ati ohun ko
Aleluya l’ohun goro. Amin.
No comments:
Post a Comment